Monday 8 October 2018

LYRICS: Evangelist Niyi Adedokun Tani Eniyan Olorun


Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan ní tèmi.
Kii ṣe pé orí mi kò pé rara
Lórí gbolohun ọrọ ti mo sọ jade
Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹni ṣi mi túmọ̀
Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan ní tèmi.

Mo fẹ́ sọ ìtàn kékeré kan ó, àrà mi
Fún gbogbo onigbagbọ inú ayé o
Láti fi hàn pé tal'eniyan Ọlọ́run
Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan ní tèmi.

Ọba kan mbẹ láyé àtijọ́
To sì ni ọmọbìnrin awẹlẹ́wá kan
Ẹni tó ti tó àkókò fún láti ni ọkọ
Lọ bá tọ bàbà rẹ wípé
E, baba mi, ó ti tó àkókò fún mi láti ni ọkọ
Ènìyàn Ọlọ́run ni mo sì nwa láti fẹ́
Mo fẹ́ kẹ tọ mi sọ́nà ni mo ṣe wa ó a
Ọba dórí kodò títi, ó sì dúpẹ́
Fún igbesẹ to awẹlẹ́wá gbe
Ó sì ṣe ìlérí ènìyàn Ọlọ́run fun
Taleniyan Ọlọ́run ò a
Leyin ti awẹlẹ́wá wọ inú ilé lo
Kabiyesi ranṣẹ sì Olú-ọdẹ ìlú
Láti wa fún ọrọ ìjíròrò pàtàkì.
Dìde t'Olú-ọdẹ de
Kabiyesi wí fun
Mo ń wá ènìyàn Ọlọ́run láàrin ìlú
Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan ní tèmi
Íwọ ni mo sì fẹ́ rán niṣẹ
Láti bá mi wa ènìyàn Ọlọ́run kiri o
L'ọjọ́ tí ìsinmi tó ń bọ̀ yí
Mo fẹ́ kó múra pẹ̀lú ada, ìbọn, ọkọ, ọbẹ̀
Kò lọ dúró s'orita
Ẹnikẹ́ni to bá ti rí tó bá fẹ́ wọ inú ilé ìsìn
Bíi léèrè pé ṣe ènìyàn Ọlọ́run ni
So fún pé Ọlọ́run ṣẹ̀ tí ọ ó sì fẹ́ gba ẹsan
Fi ada ha'lẹ bí ẹnipé ó fẹ́ pá wọn
Gbé ìbọn s'ókè bí ẹnipé ó fẹ́ ṣana si
Ẹnikẹni ti ko ba sẹ Ọlọ́run, mú wá fún mi.

L'òwúrọ̀ kùtùkùtù, lọ́jọ́ ìsinmi
Olú-ọdẹ tí lọ dènà tó lọ s'íle ìsin
Àwọn ẹgbẹ́ akọrin lo kọ́kọ́ yọ'ju
Pẹ̀lú aṣọ funfun l'ara àti ìwé orin
Olú-ọdẹ dẹru báwọn pé tá l'ènìyàn Ọlọ́run
Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan l'ara rẹ.

Ẹgbẹ́ akọrin p'ohunda wọn ní rárà
Wọn làwọn kii ṣe ènìyàn Ọlọ́run
Ere asa pajude, kò ṣe f'ẹnu sọ
Ọ̀gá akọrin lọ kò rántí ìwé orin
Kọ́kọ́rọ́ ilé duuru tí bọ sọnù
Guitar tí wọn gbé dání, Olú-ọdẹ tí gbe
Ẹgbẹ́ akọrin kò lè jìyà f'ẹsẹ Ọlọ́run
Nítorí ada, ìbọn, ọkọ
Tá l'ènìyàn Ọlọ́run ó à?

Gbogbo obìnrin ìjọ lo sa padà sílè
Àwọn ọkùnrin pẹ̀lú kò dúró mú fìlà
Kò pẹ, kò jìnà títí, àwọn alàgbà de
Pelu Bíbélì tí wọ́n fi nka lesson lọwọ
 Olú-ọdẹ bi wọn pé tá l'ènìyàn Ọlọ́run o
Ọlọ́run sẹ̀  mi ò mọ sì fẹ́ gba ẹsan ní tèmi.

Baba ìjọ lo gb'ẹnu àwọn alàgbà sọ̀rọ̀
Ó ní alàgbà làwọn, wọn kii ṣe t'Ọlọ́run
Kò sí yẹ kí àwọn jìyà ẹsẹ̀ Olódùmarè
Ìwé ẹri ti wọn fún wa, wọn kò kọ sínú rẹ
Pé a ó y'àro ẹsẹ Ọlọ́run l'ara wa
Awa ko mọ Ọlọ́run ríi ó, Olú-ọdẹ.

Ǹjẹ́ tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?

Àwọn alàgbà sá padà sílè nítorí ada, ìbon, ọkọ, ọbẹ̀.

Àlùfáà tó so collar m'ọrun pẹ̀lú de
Olú-ọdẹ bèrè pé ṣe ènìyàn Ọlọ́run ní
Torí pe Ọlọ́run sẹ̀ hun òhun sì fẹ́ gba ẹsan
Àlùfáà bá ń bẹbẹ pelu ohun kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́
Wọn gbé mi wá sí ilẹ yí ni
Ń ó sì padà sílè
Èmi kò gbà ikú mọ isẹ ìránṣẹ́ mi
Èmi kii se ènìyàn Ọlọ́run  l'àlùfáà wí o
nítorí ada, ìbon, ọkọ, ọbẹ̀
Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?

Kò pẹ ni Ìgbàgbọ́sọwọn dé
Pẹ̀lú orin ìgboyà lẹ́nu rẹ jáde
Olú-ọdẹ tún bèrè bí ìṣe rẹ
Ìgbàgbọ́sọwọn ni ènìyàn Ọlọ́run lohun
Ní kíkú ni yiye, ohun gba Jésù gbọ́
Kini yí ọ ya ohun kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run
Ìpọ́njú tàbí ada tàbí ogun ìbọn
Ènìyàn Ọlọ́run ni mí ó a.

Ènìyàn Ọlọ́run ni yi ni tòótọ́
Kò bẹru ada àti ìbọn Olú-ọdẹ
Lọ bá pè awẹlẹ́wa jáde ní sójú gbogbo ènìyàn
Ó ní kí Ìgbàgbọ́sọwọn fi awẹlẹ́wa ṣ'aya

Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?

Àbọ̀ mi re ó, ọmọ ènìyàn
Oríṣiríṣi Olú-ọdẹ lọ nbẹ
Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó, ẹyin ara
Ogun ẹlòmíràn ṣá ni ogun ai r'ọmọ bi
Olú-ọdẹ ẹlòmíràn ṣá ni ifẹ owó
Èyí tó ti mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?
Tábà sọ fún onigbagbọ miran nínú ayé
Pé kò fi ọwọ ara rẹ ṣana sì Bíbélì
Ẹlòmíràn a sì ṣe nítorí ogun
Igbagbọ tí ẹlòmíràn gba l'ori ahọn ni
Tí wọn ba sọ pe k'olòmíràn kò ṣe onigbagbọ
Bi ko ba se o, wọn ní láti pá ni
Bi a ba sọ pe k'oníkálukú máa sun Bíbélì
Ọ̀pọ̀ ni yóò p'ohunda pé wọn kò mọ Ọlọ́run
Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?

Irọ́kẹ̀kẹ̀ ogun ẹsin ti a ti ń ri
To bá ṣe pé ọpọ ó ṣeé ṣe ni ara
Ọ̀pọ̀ ni ó bá ti di abọ̀rìṣà ni gbogbo ọ̀nà
Onigbagbọ ni lati kíyèsara gidi
Idanwo kí idanwo tó bá de ká rọju duro
Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a?
Evangelist Nìyí Adedokun, Ọlọ́run sẹ̀ mí

Òpin ọrọ mi náà ni yi o ara
Kii ṣe pé èmi ni Ọlọ́run ṣẹ
Òwe ni mo fi ọ̀rọ̀ yi pa
Mo fẹ́ kẹ gbọ́
Mo sì mọ pe àti rí àbọ̀ ìtàn mi
Ǹjẹ́ kí oníkálukú ó kíyèsara
Di ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ nínú ogún láyé
Di ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ nínú ogún ọ̀tẹ̀
Ǹjẹ́ èèyàn Ọlọ́run níwọ̀ olugbò?
Jọ̀wọ́ kíyèsara niwọnba tó kú kí ayé tó pín
Tá l'ènìyàn Ọlọrun ó a? (till fade)

1 comment:

  1. God bless you richly ma for this great work, to preserve the lyrics of this great message song

    May the Lord uphold us in Him, so that we can continue steadfastly and unrelentingly upholding the faith till the end. Amen

    ReplyDelete

l love to read from you.