Ipe na n dun kikan is another old gold in the pantheon of Yoruba gospel songs. Ìpè náà ń dún kíkan by Evangelist Akin Adebayo is an '80s baby, and I was sure surprised to hear it today. I was so happy that I took time to write out the lyrics.
Here are the lyrics to Ìpè náà ń dún kíkan - Evang. Akin Adebayo.
Ọ̀rọ̀ ìgbàlà ńmo gbé dé
Ará mí yé, ẹ dìde
Ó yá ká jọ gbọ́
Ọ̀rọ̀ ìgbàlà mo gbé dé
Ará mí yé, ẹ dìde
Ó yá ká jọ gbọ́
Ẹ ké s'ẹbí, ẹ ké s'àrà
Ẹ ké sí gbogbo ènìyàn
Ènìyàn tí ń bẹ l'ẹ̀hìnkùlé
Ẹ bá mi ké sí gbogbo wọn
(instrumental interlude)
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ó ń pè ọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
Ìpè náà ń dún
Tètè bá Ọlọ́run l'àjà
Ìpè náà ń dún
Jésù dúró lẹ́nu ọ̀nà rẹ
Ó ń pè ọ, ẹlẹ́ṣẹ̀ ó, ẹlẹ́ṣẹ̀ ó!
Mí a bọ̀, Olùgbàlà máa ń retí rẹ
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ó ń pè ọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
Ìpè náà ń dún
Tètè bá Ọlọ́run l'àjà
Ìpè náà ń dún
Jésù ń ké kankan
Jésù ń ké
Jésù ń ké kankan
Pé ẹlẹ́ṣẹ̀ máa bọ̀
Sá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ó ń pè ọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
Ìpè náà ń dún
Tètè bá Ọlọ́run l'àjà
Ìpè náà ń dún
Ní àsẹ̀ dídá ayé
Olúwa dá wa sínú ọgbà ìdẹ̀ra
Ka máà jẹ, ka máà mu
Ka sì máà gbé láì fòyà
Àìní ìtẹ́lọ́rùn ènìyàn
Ló mú wa kùnà ògo Ọlọ́run
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ìpè náà ń dún kíkan
Ìpè náà ń dún
Ó ń pè ọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
Ìpè náà ń dún
Tètè bá Ọlọ́run l'àjà
Ìpè náà ń dún
(instrumental interlude)
Ọ̀nà ìgbàlà míràn kò máà tún sí
Jésù Kristi lọ̀nà ìyè aráyé gbogbo
Má jẹ́ ń ṣì nà lọ́nà rẹ
Ọlọ́run mi, mo bẹ̀ ọ́
Ọ̀nà ìgbàlà míràn kò máà tún sí
Jésù Kristi lọ̀nà ìyè aráyé gbogbo
Má jẹ́ ń ṣì nà lọ́nà rẹ
Ọlọ́run mi, mo bẹ̀ ọ́
Máà ṣiṣẹ́ mímọ́
Kí ń lè dé ilé ìyè
Máà ṣiṣẹ́ pípé o
Kí ń lè dé ilé ògo
Ilé mí ń bẹ lókè
Ilé mí ń bẹ lókè ọ̀run
Ilé mí ń bẹ lókè
Ilé mí ń bẹ lókè ọ̀run
Baba mú mí dé bẹ̀
Ilé mí ń bẹ lókè ọ̀run
Ìbẹ̀rẹ̀ kìí ṣe oníṣẹ́
Á fí ẹni báà ṣé d'òpin
Wá mú wa ṣe àṣeyege
Máà ṣiṣẹ́ mímọ́
Kí ń lè dé ilé ìyè
Máà ṣiṣẹ́ pípé o
Kí ń lè dé ilé ògo
Ilé mí ń bẹ lókè
Ilé mí ń bẹ lókè ọ̀run
(instrumental interlude)
Jésù fẹ́ràn rẹ
Ó ń pè ọ, máà bọ̀ o
Áà ó fẹ́ mí
Má ṣe kọ ìpè náà, ọmọ Ọlọ́run
Áà ó fẹ́ mí
Ẹ wá wo ẹni tó f'ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ f'èmi ẹlẹ́ṣẹ̀
Áà ó fẹ́ mí
Ó fẹ́ mí, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀
Áà ó fẹ́ mí, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀
Áà ó fẹ́ mí, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀
Ikú oró rẹ̀ o, omi tó yọ ní'ha rẹ̀
Ó tó fún mi!
Gbogbo aráyé mo fẹ́ kẹ mọ̀
Ọ̀nà ìgbàlà míràn kò sì lẹ́yìn ẹ̀jẹ̀ Jésù ó
Bí ayé àti ọ̀run bá ń kọjá lọ
Kíun nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò le lọ láláí ṣẹ
Mò ń gbé nínú Ọlọ́run kọrin f'aráyé
Mò ń gbé nínú Ọlọ́run s'ọ̀rọ̀ ìgbàlà f'àwọn ènìyàn
Ọ̀rọ̀ tí ń gbé inú wúńdíá ṣ'ọlá
Ó ń gbé inú adélébọ̀ ṣ'ògo
Àtètèkọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ tí wà
Ọ̀rọ̀ ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run
Baba wá sọ'ra rẹ jáde
Ojìgìjígí aláṣẹ òtítọ́, aládé mímọ́
Ọba tó fàde rera bí aṣọ
Mo súnmọ́ Ọba níwọ̀n ẹgbẹ̀fà
Mo bẹ̀rẹ̀ f'ọba níwọ̀n egbèje
Mo tẹríba níwájú baba rere
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Ó lè jẹ́ l'óni tàbí l'ọ́la, mi ò mà mọ̀
Ó lè jẹ́ l'ọ̀sán tàbí l'alẹ́, mi ò lè sọ
Tó bá dé, tó bá dé,
Ńg ó f'ayọ̀ pàdé Olúwa mi o
Tó bá dé
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Ó lè jẹ́ l'óni tàbí l'ọ́la, mi ò mà mọ̀
Ó lè jẹ́ l'ọ̀sán tàbí l'alẹ́, mi ò lè sọ
Tó bá dé, tó bá dé,
Ńg ó f'ayọ̀ pàdé Olúwa mi o
Tó bá dé
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Ó lè jẹ́ l'óni tàbí l'ọ́la, mi ò mà mọ̀
Ó lè jẹ́ l'ọ̀sán tàbí l'alẹ́, mi ò lè sọ
Tó bá dé, tó bá dé,
Ńg ó f'ayọ̀ pàdé Olúwa mi o
Tó bá dé
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Ó lè jẹ́ l'óni tàbí l'ọ́la, mi ò mà mọ̀
Ó lè jẹ́ l'ọ̀sán tàbí l'alẹ́, mi ò lè sọ
Tó bá dé, tó bá dé,
Ńg ó f'ayọ̀ pàdé Olúwa mi o
Tó bá dé
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Dídé Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, màá ṣọ́nà
Ó lè jẹ́ l'óni tàbí l'ọ́la, mi ò mà mọ̀
Ó lè jẹ́ l'ọ̀sán tàbí l'alẹ́, mi ò lè sọ
Tó bá dé, tó bá dé,
Ńg ó f'ayọ̀ pàdé Olúwa mi o
Tó bá dé
Tí Jésù bá pè ọ́, wá.
Má ṣe fi ìgbàlà rẹ d'ọ̀la
Ó ń dúró o, lẹ́nu ọ̀nà
Ó ń dúró
Tí Jésù bá pè ọ́, wá.
Sáré tete máà bọ̀, ọmọ
Ó ń dúró o, lẹ́nu ọ̀nà
Ó ń dúró
Tí Jésù bá pè ọ́, wá.
Sáré tete o, sáré wá
Ó ń dúró o, lẹ́nu ọ̀nà
Ó ń dúró
Tí Jésù bá pè ọ́, wá.
Má ṣe kọ ìpè náà
Ó ń dúró o!
No comments:
Post a Comment
l love to read from you.